1 Kings 4:13 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Bẹngeberi ni alákòóso ìlú Ramoti Gileadi, (ati àwọn ìletò Jairi, ọmọ Manase, tí ó wà ní ilẹ̀ Gileadi, ati agbègbè Arigobu, ní ilẹ̀ Baṣani. Gbogbo wọn jẹ́ ọgọta ìlú ńláńlá tí wọn mọ odi yíká, bàbà ni wọ́n sì fi ṣe ọ̀pá ìdábùú ìlẹ̀kùn ẹnubodè wọn.)
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ọmọ Geberi ni Ramoti-Gileadi; tirẹ̀ ni awọn ileto Jairi, ọmọ Manasse, ti mbẹ ni Gileadi; tirẹ̀ si ni apa Argobu, ti mbẹ ni Baṣani, ọgọta ilu ti o tobi, ti o li odi ati ọpa-idabu idẹ.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Bẹni-Gébérì ní Rámótì-Gílíádì; tirẹ̀ ni àwọn ìletò Jáírì ọmọ Mànásè tí ń bẹ ní Gílíádì, tirẹ̀ sì ni agbégbé Ágóbù, tí ń bẹ ní Básánì, ọgọ́ta (60) ìlú tí ó tóbi pẹ̀lú odi tí ẹnu ọ̀nà rẹ̀ jẹ́ irin.