1 Kings 4:19 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Geberi, ọmọ Uri, ni alákòóso agbègbè Gileadi, níbi tí Sihoni ọba àwọn ará Amori ati Ogu ọba Baṣani ti jọba tẹ́lẹ̀ rí. Lẹ́yìn àwọn alákòóso mejeejila wọnyi, alákòóso àgbà kan tún wà fún gbogbo ilẹ̀ Juda.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Geberi, ọmọ Uri wà ni ilẹ Gileadi ni ilẹ Sihoni, ọba awọn ara Amori, ati Ogu, ọba Baṣani: ijoye kan li o si wà ni ilẹ na.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Gébérì ọmọ Úrì ní Gílíádì; orílẹ̀ èdè Ṣíhónì ọba àwọn ará Ámórì àti orílẹ̀ èdè Ógù ọba Básánì. Òun nìkan ni ìjòyè lórí ilẹ̀ náà.