1 Kings 4:21 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Solomoni jọba lórí gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè, láti odò Yufurate títí dé ilẹ̀ Filistia, títí dé ààlà ilẹ̀ àwọn ará Ijipti. Wọ́n ń san ìṣákọ́lẹ̀ fún un, wọ́n sì ń sìn ín ní gbogbo ọjọ́ ayé rẹ̀.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Solomoni si jọba lori gbogbo awọn ọba lati odò titi de ilẹ awọn ara Filistia, ati titi de eti ilẹ Egipti: nwọn nmu ọrẹ wá, nwọn si nsìn Solomoni ni gbogbo ọjọ aiye rẹ̀.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Sólómónì sì ń ṣàkóso lórí gbogbo àwọn ijọba láti odò Éjíbítì títí dé ilẹ̀ àwọn ará Fílístínì, àti títí dé etí ilẹ̀ Éjíbítì. Àwọn orílẹ̀ èdè yìí ń mú owó òde wá, wọ́n sì ń sin Sólómónì ní gbogbo ọjọ́ ayé rẹ̀.