1 Kings 4:24 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Solomoni jọba lórí gbogbo ilẹ̀ tí ó wà ní apá ìwọ̀ oòrùn odò Yufurate, láti ìlú Tifisa, títí dé ìlú Gasa, ati lórí gbogbo àwọn ọba tí wọ́n wà ní apá ìwọ̀ oòrùn odò Yufurate; alaafia sì wà láàrin òun ati àwọn agbègbè tí ó wà ní àyíká rẹ̀.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nitori on li o ṣe alaṣẹ lori gbogbo agbègbe ni iha ihin odò, lati Tifsa titi de Gasa, lori gbogbo awọn ọba ni iha ihin odò: o si ni alafia ni iha gbogbo yi i kakiri.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nítorí òun ni ó ṣakóso lórí gbogbo agbègbè ní ìhà ìwọ̀-oòrùn Éfúrátì, láti Tífísà títí dé Gásà, ó sì ní àlàáfíà ní gbogbo ìlú tí ó káàkiri.