1 Kings 4:28 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Wọn a sì máa mú ọkà baali ati koríko wá fún àwọn ẹṣin tí ń wa kẹ̀kẹ́ ogun ati àwọn ẹṣin tí wọ́n fi ń ṣiṣẹ́. Olukuluku a máa mú ohun tí wọ́n bù fún un wá sí ibi tí wọ́n ti nílò rẹ̀.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ọkà barle pẹlu, ati koriko fun ẹṣin ati fun ẹṣin sisare ni nwọn mu wá sibiti o gbe wà, olukuluku gẹgẹ bi ilana tirẹ̀.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Wọ́n tún máa ń mú ọkà báálì àti kóríko fún ẹsin àti fún ẹsin sísáré wá pẹ̀lú sí ibi tí ó yẹ, olúkúlùkù gẹ́gẹ́ bí ìlànà tirẹ̀.