1 Kings 4:33 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Ó sọ nípa igi, ó bẹ̀rẹ̀ láti orí igi kedari ti ilẹ̀ Lẹbanoni, títí kan Hisopu tí ó ń hù lára ògiri. Ó sọ nípa àwọn ẹranko, ati àwọn ẹyẹ, àwọn ohun tí ń fi àyà fà ati àwọn ẹja.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
O si sọ̀rọ ti igi, lati kedari ti mbẹ ni Lebanoni, ani titi de hissopu ti nhu lara ogiri: o si sọ̀ ti ẹranko pẹlu, ati ti ẹiyẹ, ati ohun ti nrako, ati ti ẹja.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ó sì sọ̀rọ̀ ti igi, láti Kédárì tí ń bẹ ní Lébánónì dé Hísópù tí ń dàgbà lára ògiri. Ó sì tún sọ ti àwọn ẹranko àti ti àwọn ẹyẹ, àti ohun tí ń rákò àti ti ẹja.