1 Kings 4:7 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Solomoni yan àwọn mejila gẹ́gẹ́ bí alákòóso ní ilẹ̀ Israẹli. Àwọn ni wọ́n ń ṣe ètò àtikó oúnjẹ jọ ní agbègbè wọn, fún ìtọ́jú ọba ati gbogbo àwọn tí ń gbé ààfin ọba. Ẹnìkọ̀ọ̀kan wọn á máa pèsè oúnjẹ fún oṣù kọ̀ọ̀kan ninu ọdún kọ̀ọ̀kan.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Solomoni si ni ijoye mejila lori gbogbo Israeli, ti o npèse onjẹ fun ọba ati agbo-ile rẹ̀; olukuluku li oṣu tirẹ̀ li ọdun ni npese.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Sólómónì sì tún ní ìjòyè méjìlá lórí gbogbo agbégbé Ísírẹ́lì, tí wọ́n ń pèsè oúnjẹ fún ọba àti agbo ilé rẹ̀. Olúkúlùkù ní láti pèsè fún oṣù kan ní ọdún.