1 Kings 5:1 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Nígbà tí Hiramu, ọba Tire, gbọ́ pé Solomoni ni ó gun orí oyè lẹ́yìn baba rẹ̀, ó rán oníṣẹ́ sí i; nítorí ọ̀rẹ́ ni òun ati Dafidi, wọ́n sì fẹ́ràn ara wọn.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
HIRAMU, ọba Tire, si rán awọn iranṣẹ rẹ̀ si Solomoni; nitoriti o ti gbọ́ pe, a ti fi ororo yàn a li ọba ni ipò baba rẹ̀: nitori Hiramu ti fẹràn Dafidi li ọjọ rẹ̀ gbogbo.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nígbà tí Hírámù ọba Tírè sì gbọ́ pé a ti fi òróró yan Sólómónì ní ọba ní ipò Dáfídì bàbá rẹ̀, ó sì rán àwọn ikọ̀ rẹ̀ sí Sólómónì, nítorí ó ti fẹ́ràn Dáfídì ní ọjọ́ rẹ̀ gbogbo.