1 Kings 5:6 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Nítorí náà, pàṣẹ fún àwọn iranṣẹ rẹ, kí wọ́n bá mi gé igi kedari ní Lẹbanoni. Àwọn iranṣẹ mi yóo bá wọn ṣiṣẹ́ pọ̀, n óo sì san iyekíye tí o bá bèèrè fún owó iṣẹ́ wọn. Gẹ́gẹ́ bí ìwọ náà ti mọ̀, àwọn iranṣẹ mi kò mọ̀ bí a tií gé igi ìkọ́lé bí àwọn ará Sidoni.”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Njẹ nisisiyi, paṣẹ ki nwọn ki o ke igi kedari fun mi lati Lebanoni wá, awọn ọmọ ọdọ mi yio si wà pẹlu awọn ọmọ ọdọ rẹ, iwọ ni emi o si sanwo ọyà awọn ọmọ ọdọ rẹ fun, gẹgẹ bi gbogbo eyi ti iwọ o wi: nitoriti iwọ mọ̀ pe, kò si ẹnikan ninu wa ti o mọ̀ bi a ti ike igi bi awọn ara Sidoni.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
“Nítorí náà ni kí o pàṣẹ pé kí wọn kí ó gé igi Kédárì Lébánónì fún mi wá. Àwọn ènìyàn mi yóò ṣiṣẹ́ pẹ̀lú tìrẹ, Èmi yóò sì san owó ọ̀yà tí ìwọ bá ránṣẹ́ fún àwọn ènìyàn rẹ. Ìwọ mọ̀ pé, a kò ní ẹnìkan nínú wa tí ó mọ bí a ti ń gé igi bí àwọn ará Ṣídónì.”