1 Kings 5:7 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Inú ọba Hiramu dùn pupọ nígbà tí wọ́n jíṣẹ́ Solomoni fún un. Ó ní, “Ẹni ìyìn ni OLUWA lónìí, nítorí pé ó fún Dafidi ní ọlọ́gbọ́n ọmọ, láti jọba lórí orílẹ̀-èdè ńlá yìí.”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
O si ṣe, nigbati Hiramu gbọ́ ọ̀rọ Solomoni, o yọ̀ pipọ, o si wipe, Olubukún li Oluwa loni, ti o fun Dafidi ni ọmọ ọlọgbọ́n lori awọn enia pupọ yi.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nígbà tí Hárámù sì gbọ́ iṣẹ́ Sólómónì, inú rẹ̀ sì dùn gidigidi, ó sì wí pé, “Ògo ni fún OLÚWA lónìí, nítorí tí ó ti fún Dáfídì ní ọlọgbọ́n ọmọ láti sàkóso àwọn ìlú ńlá yìí.”