1 Kings 5:9 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Àwọn iranṣẹ mi yóo gé igi náà ní Lẹbanoni, wọn yóo kó wọn wá sí etí òkun. Wọn óo dì wọ́n ní ìdì kọ̀ọ̀kan kí wọ́n lè tù wọ́n gba ojú òkun lọ sí ibikíbi tí o bá fẹ́. Wọn óo tú wọn kalẹ̀ níbẹ̀, wọn óo sì kó wọn fún àwọn iranṣẹ rẹ. Ohun tí mo fẹ́ kí o mójútó ni oúnjẹ tí èmi ati ìdílé mi óo máa jẹ.”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Awọn ọmọ ọdọ mi yio mu igi na sọkalẹ lati Lebanoni wá si okun: emi o si fi wọn ṣọwọ si ọ ni fifó li omi okun titi de ibi ti iwọ o nà ika si fun mi, emi o si mu ki nwọn ki o ko wọn sibẹ, iwọ o si ko wọn lọ: iwọ o si ṣe ifẹ mi, lati fi onjẹ fun ile mi.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Àwọn ènìyàn mi yóò mú igi náà sọ̀kalẹ̀ láti Lébánónì wá sí òkun, èmi ó sì fi wọ́n ránṣẹ́ sí ọ ní fífò lójú omi òkun títí dé ibi tí ìwọ ó na ìka sí fún mi. Níbẹ̀ ni èmi yóò ti yà wọ́n sọ́tọ̀, ìwọ yóò sì kó wọn lọ. Ìwọ yóò sì gba ìfẹ́ mi nípa pípèsè oúnjẹ fún ilé mi.”