1 Kings 6:1 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Nígbà tí ó di ọrinlenirinwo (480) ọdún tí àwọn ọmọ Israẹli kúrò ní ilẹ̀ Ijipti, ní ọdún kẹrin tí Solomoni gun orí oyè ní Israẹli, ní oṣù Sifi, tíí ṣe oṣù keji ọdún náà, ni ó bẹ̀rẹ̀ kíkọ́ ilé OLUWA.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
O si ṣe, ni ọrinlenirinwo ọdun, lẹhin igbati awọn ọmọ Israeli jade kuro ni ilẹ Egipti, li ọdun kẹrin ijọba Solomoni lori Israeli, li oṣu Sifi ti iṣe oṣu keji, li o bẹ̀rẹ si ikọ́ ile fun Oluwa.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ní ìgbà tí ó pe ọ̀rìnlénírinwó ọdún l (488) ẹ́yìn ìgbà tí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ti jáde kúrò ní ilẹ̀ Éjíbítì, ní ọdún kẹrin ìjọba Sólómónì lórí Ísírẹ́lì, ní oṣù Sífì, tí ń ṣe oṣù kejì, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí kọ́ ilé OLÚWA.