1 Kings 6:15 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Pákó igi kedari ni ó fi bo ara ògiri ilé náà ninu, láti òkè dé ilẹ̀. Pákó igi sipirẹsi ni wọ́n sì fi tẹ́ gbogbo ilẹ̀ rẹ̀.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
O si fi apako kedari tẹ́ ogiri ile na ninu, lati ilẹ ile na de àja rẹ̀; o fi igi bò wọn ninu, o si fi apako firi tẹ́ ilẹ ile na.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ó sì fi pákó Kédárì tẹ́ ògiri ilé náà nínú, láti ilẹ̀ ilé náà dé àjà rẹ̀, ó fi igi bò wọ́n nínú, ó sì fi pákó fírì tẹ́ ilẹ̀ ilé náà.