1 Kings 6:16 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Wọ́n kọ́ yàrá kan tí wọn ń pè ní Ibi-Mímọ́-Jùlọ, sí ọwọ́ ẹ̀yìn ilé ìsìn náà. Gígùn rẹ̀ jẹ́ ogún igbọnwọ, pákó kedari ni wọn fi gé e láti òkè dé ilẹ̀.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
O si kọ́ ogún igbọnwọ ni ikangun ile na, lati ilẹ de àja ile na li o fi apako kedari kọ́, o tilẹ kọ́ eyi fun u ninu, fun ibi-idahùn, ani ibi-mimọ́-julọ.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ó pín ogún ìgbọ̀nwọ́ sí ẹ̀yìn ilé náà, láti ilẹ̀ dé àjà ilé ni ó fi pákó kọ́, èyí ni ó kọ sínú, fún ibi tí a yà sí mímọ́ àní ibi mímọ́ jùlọ.