1 Kings 6:20 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Gígùn ibi mímọ́ ti inú yìí jẹ́ ogún igbọnwọ, ó fẹ̀ ní ogún igbọnwọ, gíga rẹ̀ náà sì jẹ́ ogún igbọnwọ. Ojúlówó wúrà ni wọ́n fi bo gbogbo ibi mímọ́ náà; wọ́n sì fi pákó igi kedari ṣe pẹpẹ kan sibẹ.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ibi-mimọ́-julọ na si jasi ogún igbọnwọ ni gigùn, li apa ti iwaju, ati ogún igbọnwọ ni ibú, ati ogún igbọnwọ ni giga rẹ̀; o si fi wura ailadàlu bò o, bẹ̃li o si fi igi kedari bò pẹpẹ.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nínú ibi mímọ́ náà sì jẹ́ ogún (20) ìgbọ̀nwọ́ ní gígùn, ogún ìgbọ̀nwọ́ ní ìbú, àti ogún ìgbọ̀nwọ́ ní gíga. Ó sì fi kìkì wúrà bo inú rẹ̀ ó sì fi igi Kédárì bo pẹpẹ rẹ̀.