1 Kings 6:27 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Ó gbé wọn kalẹ̀ sí ẹ̀gbẹ́ ara wọn ninu Ibi-Mímọ́-Jùlọ. Àwọn mejeeji na ìyẹ́ wọn tí ó fi jẹ́ pé ọ̀kan ninu àwọn ìyẹ́ Kerubu kinni kan ògiri yàrá ní ẹ̀gbẹ́ kan, ọ̀kan ninu àwọn ìyẹ́ Kerubu keji sì kan ògiri yàrá ní ẹ̀gbẹ́ keji. Ìyẹ́ keji Kerubu kinni ati ìyẹ́ kinni Kerubu keji sì kan ara wọn ní ààrin yàrá náà.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
O si fi awọn kerubu sinu ile ti inu lọhun, nwọn si nà iyẹ-apa kerubu na, tobẹ̃ ti iyẹ-apa ọkan si kàn ogiri kan, ati iyẹ-apa kerubu keji si kàn ogiri keji: iyẹ-apa wọn si kàn ara wọn larin ile na.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ó sì gbé àwọn kérúbù náà sínú ilé ti inú lọ́hùn ún, pẹ̀lú ìyẹ́ apá wọn ní nínà jáde. Ìyẹ́ apá kérúbù kan sì kan ògiri kan, nígbà tí ìyẹ́-apá èkejì sì kan ògiri kejì, ìyẹ́ apá wọn sì kan ara wọn láàrin yàrá náà.