1 Kings 6:38 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Ninu oṣù Bulu, ní ọdún kọkanla ìjọba Solomoni ni wọ́n kọ́ ilé ìsìn náà parí patapata, ó sì rí bí wọ́n ti ṣètò pé kó rí gẹ́lẹ́. Ọdún meje ni ó gba Solomoni láti parí rẹ̀.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ati li ọdun kọkanla, li oṣu Bulu, ti iṣe oṣu kẹjọ, ni ile na pari jalẹ-jalẹ, pẹlu gbogbo ipin rẹ̀, gẹgẹ bi gbogbo eyi ti o yẹ: o si fi ọdun meje kọ́ ọ.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ní ọdún kọkànlá ní oṣù Búlù, oṣù kẹjọ, a sì parí ilé náà jálẹ̀ jálẹ̀, pẹ̀lú gbogbo ìpín rẹ̀, gẹ́gẹ́ bí gbogbo èyí tí ó yẹ. Ó sì lo ọdún méje ní kíkọ́ ilé náà.