1 Kings 6:7 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Níbi tí wọ́n ti ń fọ́ òkúta ni wọ́n ti gbẹ́ gbogbo òkúta tí wọ́n fi kọ́ ilé ìsìn náà, wọn kò lo òòlù, tabi àáké, tabi ohun èlò irin kankan ninu tẹmpili náà nígbà tí wọ́n ti ń kọ́ ọ lọ.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ile na, nigbati a nkọ́ ọ, okuta ti a ti gbẹ́ silẹ ki a to mu u wá ibẹ li a fi kọ́ ọ, bẹ̃ni a kò si gburo mataka, tabi ãke, tabi ohun-elo irin kan nigbati a nkọ́ ọ lọwọ.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ní kíkọ́ ilé náà, òkúta tí a ti gbẹ́ sílẹ̀ kí a tó mú-un wá ibẹ̀ nìkan ni a lò, a kò sì gbúròó òòlù tàbí àáké tàbí ohun èlò irin kan nígbà tí a ń kọ́ ọ lọ́wọ́.