1 Kings 6:8 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Ninu ilé alágbèékà mẹta tí wọ́n kọ́ mọ́ ara ilé ìsìn náà, ẹnu ọ̀nà ilé tí ó wà ní ìsàlẹ̀ patapata wà ní apá gúsù ilé ìsìn náà, ó ní àtẹ̀gùn tí ó lọ sí àgbékà keji, àgbékà keji sì ní àtẹ̀gùn tí ó lọ sí àgbékà kẹta.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ilẹkun yara ãrin mbẹ li apa ọtún ile na: nwọn si fi àtẹgun ti o lọ́ri goke sinu yàra ãrin, ati lati yara ãrin bọ sinu ẹkẹta.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ẹnu-ọ̀nà yàrá ìṣàlẹ̀ sì wà ní ìhà gúṣù ilé náà; wọ́n sì fi àtẹ̀gùn tí ó lórí gòkè sínú yàrá àárin, àti láti yàrá àárin bọ́ sínú ẹ̀kẹ́ta.