1 Kings 7:12 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Ìlè mẹta mẹta òkúta gbígbẹ́ tí a fi ìlé kan igi kedari là láàrin, ni wọ́n fi kọ́ àgbàlá ńlá náà yípo. Bẹ́ẹ̀ náà sì ni àgbàlá ti inú ilé OLUWA ati yàrá àbáwọlé.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ati agbàla nla yikakiri pẹlu jẹ ọ̀wọ́ mẹta okuta gbigbẹ́, ati ọ̀wọ́ kan igi idabu ti kedari, ati fun agbala ile Oluwa ti inu lọhun, ati fun iloro ile na.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Àgbàlá ńlá náà yíkákiri ògiri pẹ̀lú ọ̀wọ́ mẹ́ta òkúta gbígbẹ́ àti ọ̀wọ́n kan igi ìdábùú ti kédárì, bí ti inú lọ́hùn ún àgbàlá ilé OLÚWA pẹ̀lú ìloro rẹ̀.