1 Kings 7:14 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
ará Tire ni baba rẹ̀, ṣugbọn opó ọmọ ẹ̀yà Nafutali kan ni ìyá rẹ̀. Baba rẹ̀ ti jáde láyé, ṣugbọn nígbà ayé rẹ̀, òun náà mọ iṣẹ́ àgbẹ̀dẹ bàbà dáradára. Huramu gbọ́n, ó lóye, ó sì mọ bí a tíí fi idẹ ṣe oríṣìíríṣìí iṣẹ́ ọnà. Ó tọ Solomoni lọ, ó sì bá a ṣe gbogbo iṣẹ́ rẹ̀.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ọmọkunrin opó kan ni, lati inu ẹya Naftali, baba rẹ̀ si ṣe ara Tire, alagbẹdẹ idẹ: on si kún fun ọgbọ́n, ati oye, ati ìmọ lati ṣe iṣẹkiṣẹ ni idẹ. O si tọ̀ Solomoni ọba wá, o si ṣe gbogbo iṣẹ rẹ̀.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
ẹni tí ìyá rẹ̀ jẹ́ opó láti inú ẹ̀yà Náfítalì àti tí baba rẹ̀ sì ṣe ará Tírè, alágbẹ̀dẹ idẹ. Hírámù sì kún fún ọgbọ́n àti òye, àti ìmọ̀ láti ṣe oríṣiríṣi iṣẹ́ idẹ. Ó wá sọ́dọ̀ Sólómónì ọba, ó sì ṣe gbogbo iṣẹ́ tí wọ́n gbé fún un.