1 Kings 7:18 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Bákan náà ni ó ṣe èso pomegiranate ní ìlà meji, ó fi wọ́n yí iṣẹ́ ọnà àwọ̀n náà po, ó sì fi dárà sí ọpọ́n tí ó wà lórí òpó. Bákan náà ni ó ṣe sí ọpọ́n orí òpó keji.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
O si ṣe awọn pomegranate ani ọ̀wọ́ meji yikakiri lara iṣẹ àwọn na, lati fi bò awọn ipari ti mbẹ loke: bẹ̃li o si ṣe fun ipari keji.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ó sì ṣe àwọn Pómégíránátè ní ọ̀wọ́ méjì yíkákiri lára iṣẹ́ ọ̀wọ̀n náà, láti fi bo àwọn ìparí ti ń bẹ lókè, ó sì ṣe bẹ́ẹ̀ fún ìparí kejì.