1 Kings 7:2 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Ọ̀kan ninu àwọn ilé tí ó kọ́ sí ààfin náà ni Ilé Igbó Lẹbanoni. Ilé náà gùn ní ọgọrun-un (100) igbọnwọ, fífẹ̀ rẹ̀ jẹ́ aadọta igbọnwọ, ó sì ga ní ọgbọ̀n igbọnwọ. Orí òpó igi kedari, tí wọ́n na ọ̀pá àjà igi kedari lé, ni wọ́n kọ́ ọ lé.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
O kọ́ ile-igbó Lebanoni pẹlu; gigùn rẹ̀ jasi ọgọrun igbọnwọ, ati ibú rẹ̀ adọta igbọnwọ, ati giga rẹ̀ ọgbọ̀n igbọnwọ, lori ọ̀wọ́ mẹrin opó igi kedari, ati idabu igi kedari lori awọn opó na.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ó kọ́ ilé igbó Lébánónì pẹ̀lú; gígùn rẹ̀ sì jẹ́ ọgọ́rùn ún ìgbọ̀nwọ́, àti àádọ́ta ìgbọ̀nwọ́ ní ìbú rẹ̀ àti gíga rẹ̀ ọgbọ̀n ìgbọ̀nwọ́; pẹ̀lú ọwọ́ mẹ́rin igi kédárì, àti ìdábú igi kédárì lórí òpó náà.