1 Kings 7:20 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Ọpọ́n kọ̀ọ̀kan wà lórí òpó mejeeji, lórí ibi tí ó yọ jáde tí ó rí bìrìkìtì lára àwọn òpó, lẹ́gbẹ̀ẹ́ iṣẹ́ ọnà náà. Igba èso pomegiranate ni wọ́n fi yí àwọn òpó náà ká ní ọ̀nà meji. Bẹ́ẹ̀ ló ṣe sí òpó keji pẹlu.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ati awọn ipari lori ọwọ̀n meji na wà loke: nwọn si sunmọ ibi ti o yọ lara ọwọ̀n ti o wà nibi iṣẹ àwọn: awọn pomegranate jẹ igba ni ọ̀wọ́ yikakiri, lori ipari keji.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Lórí àwọ̀n ìparí ọ̀wọ́n méjì náà lókè, wọ́n sì súnmọ́ ibi tí ó yẹ lára ọ̀wọ̀n tí ó wà níbi iṣẹ́ àwọ̀n, wọ́n sì jẹ́ igba (200) pómégíránátè ní ọ̀wọ́ yíkákiri.