1 Kings 7:23 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Ó ṣe agbada omi rìbìtì kan. Jíjìn rẹ̀ jẹ́ igbọnwọ marun-un ààbọ̀, fífẹ̀ rẹ̀ sì jẹ́ igbọnwọ mẹ́wàá. Àyíká rẹ̀ sì jẹ́ ọgbọ̀n igbọnwọ.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
O si ṣe agbada nla didà igbọnwọ mẹwa lati eti kan de ekeji: o ṣe birikiti, giga rẹ̀ si jẹ igbọnwọ marun: okùn ọgbọ̀n igbọnwọ li o si yi i kakiri.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ó sì ṣe agbádá dídá, ó ṣe bíríkítí, ó wọn ìgbọ̀nwọ́ mẹ́wàá láti etí kan dé èkejì àti ìgbọ̀nwọ́ márùn ún ní gíga rẹ̀. Ó sì gba okùn ọgbọ̀n ìgbọ̀nwọ́ láti wọ̀n yíí ká.