1 Kings 7:24 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Wọ́n fi idẹ ṣe ọpọlọpọ agbè, wọ́n tò wọ́n ní ìlà meji sí etí agbada omi náà. Láti ilẹ̀ ni wọ́n ti ṣe àwọn agbè yìí ní àṣepọ̀ mọ́ agbada omi náà.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ati nisalẹ eti rẹ̀ yikakiri kóko wà yi i ka, mẹwa ninu igbọnwọ kan, o yi agbada nla na kakiri: a dà kóko na ni ẹsẹ meji, nigbati a dà a.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ní ìṣàlẹ̀ etí rẹ̀, kókó wà yíi ká, mẹ́wàá nínú ìgbọ̀nwọ́ kan. Ó yí agbádá náà káàkiri, a dá kókó náà ní ọ̀wọ́ méjì, nígbà tí a dá a.