1 Kings 7:25 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Wọ́n gbé agbada yìí ka orí akọ mààlúù mejila, tí wọ́n fi bàbà ṣe. Mẹta ninu àwọn mààlúù náà dojú kọ apá ìhà àríwá, àwọn mẹta dojú kọ apá ìwọ̀ oòrùn, àwọn mẹta dojú kọ apá gúsù, àwọn mẹta sì dojú kọ apá ìlà oòrùn.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
O duro lori malu mejila, mẹta nwo iha ariwa, mẹta si nwo iwọ-õrun, mẹ̃ta si nwo gusu, mẹta si nwo ila-õrun; agbada nla na si joko lori wọn, gbogbo apa ẹhin wọn si mbẹ ninu.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ó sì dúró lórí màlúù méjìlá, mẹ́ta kọjú sí àríwá, mẹ́ta sì kọjú sí ìwọ̀ oòrùn, mẹ́ta kọjú sí gúṣù, mẹ́ta sì kọjú sí ìlà oòrùn. Agbada náà sì jókòó lórí wọn, gbogbo apá ẹ̀yìn wọn sì ń bẹ nínú.