1 Kings 7:29 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
lórí àwọn ìtẹ́dìí yìí ni ó ya àwòrán àwọn kinniun, mààlúù ati ti kerubu sí. Wọ́n ṣe àwọn ọnà róbótó róbótó kan báyìí sí òkè àwọn kinniun ati akọ mààlúù náà ati sí ìsàlẹ̀ wọn.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ati lara alafo ọ̀na arin ti mbẹ lagbedemeji ni aworan kiniun, malu, ati awọn kerubu wà; ati lori ipade eti, ijoko kan wà loke: ati labẹ awọn kiniun, ati malu ni iṣẹ ọṣọ́ wà.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Lórí àlàfo ọnà àárin tí ó wà lágbedeméjì ni àwòrán kìnnìún, màlúù, àti àwọn kérúbù wà, àti lórí ìpàdé etí bákan náà. Lókè àti nísàlẹ̀ àwọn kìnnìún, màlúù sì ni iṣẹ́ ọ̀ṣọ́ wà.