1 Kings 7:30 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Olukuluku ìtẹ́lẹ̀ yìí ni ó ní àgbá kẹ̀kẹ́ idẹ mẹrin, igun mẹrẹẹrin rẹ̀ sì ní ìtẹ́lẹ̀, lábẹ́ agbada náà ni àwọn ìtẹ́lẹ̀ tí a rọ wà. A ṣe ọ̀ṣọ́ sí gbogbo igun ìtẹ́lẹ̀ náà,
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Olukuluku ijoko li o ni ayika kẹkẹ́ idẹ mẹrin, ati ọpa kẹkẹ́ idẹ: igun mẹrẹrin rẹ̀ li o ni ifẹsẹtẹ labẹ; labẹ agbada na ni ifẹsẹtẹ didà wà, ni iha gbogbo iṣẹ ọṣọ́ na.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ẹsẹ̀ kọ̀ọ̀kan sì ni kẹ̀kẹ́ idẹ mẹ́rin pẹ̀lú ọ̀pá kẹ̀kẹ́ idẹ, ọ̀kọ̀ọ̀kan ni ó ní ìfẹsẹ̀tẹ̀ lábẹ́, tí a gbẹ́, iṣẹ́ ọ̀ṣọ́ wà ní ìhà gbogbo rẹ̀.