1 Kings 7:31 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
òkè agbada náà dàbí adé tí a yọ sókè ní igbọnwọ kan, wọ́n sì ṣe iṣẹ́ ọnà aláràbarà yí etí rẹ̀ po.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ẹnu rẹ̀ ninu ipari na ati loke jẹ igbọnwọ kan: ṣugbọn ẹnu rẹ̀ yika gẹgẹ bi iṣẹ ijoko na, si jẹ igbọnwọ kan on àbọ: ati li ẹnu rẹ̀ ni ohun ọnà gbigbẹ́ wà pẹlu alafo ọ̀na arin wọn, nwọn si dọgba ni igun mẹrẹrin, nwọn kò yika.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nínú ẹsẹ̀ náà ẹnu kan wà tí ó kọ bíríkítí tí ó jìn ní ìgbọ̀nwọ́ kan. Ẹnu yìí ṣe róbótó àti pẹ̀lú iṣẹ́ ẹṣẹ̀ rẹ̀ jẹ́ ìgbọ̀nwọ́ kan àti ààbọ̀. Ní àyíká ẹnu rẹ̀ ni ohun ọnà gbígbẹ́ wà. Àlàfo ọ̀nà àárin ẹsẹ̀ náà sì ní igun mẹ́rin, wọn kò yíká.