1 Kings 7:32 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Àwọn àgbá kẹ̀kẹ́ mẹrẹẹrin wà lábẹ́ àwọn ìtẹ́dìí yìí, àṣepọ̀ mọ́ ìtẹ́lẹ̀ ni wọ́n ṣe àwọn ọ̀pá inú àgbá kẹ̀kẹ́ náà. Gíga àgbá kẹ̀kẹ́ kọ̀ọ̀kan sì jẹ́ igbọnwọ kan ààbọ̀.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ati nisalẹ alafo ọ̀na arin, ayika-kẹkẹ́ mẹrin li o wà: a si so ọpa ayika-kẹkẹ́ na mọ ijoko na; giga ayika-kẹkẹ́ kan si jẹ igbọnwọ kan pẹlu àbọ.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Kẹ̀kẹ́ mẹ́rin sì wà nísàlẹ̀ àlàfo ọ̀nà àárin a sì so ọ̀pá àyíká kẹ̀kẹ́ náà mọ́ ẹsẹ̀ náà. Gíga àyíká kẹ̀kẹ́ kan sì jẹ́ ìgbọ̀nwọ́ kan àti ààbọ̀.