1 Kings 7:35 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
A mọ ìgbátí yíká òkè àwọn ìtẹ́lẹ̀ náà, tí ó ga sókè ní ààbọ̀ igbọnwọ, ìgbátí yìí wà ní téńté orí àwọn ìtẹ́lẹ̀ náà. Àṣepọ̀ ni wọ́n ṣe òun ati ìtẹ́dìí rẹ̀.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ati loke ijoko na, ayika kan wà ti àbọ igbọnwọ: ati loke ijoko na ẹgbẹgbẹti rẹ̀ ati alafo ọ̀na arin rẹ̀ jẹ bakanna.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Lókè ẹṣẹ̀ náà ni àyíká kan wà tí ó jẹ́ ààbọ̀ ìgbọ̀nwọ́ ní jíjìn. Ẹ̀gbẹ́ etí rẹ̀ àti àlàfo ọ̀nà àárin rẹ̀ ni a ṣo mọ́ òkè ẹsẹ̀ náà.