1 Kings 7:36 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Ó ya àwòrán àwọn kerubu, ati kinniun ati ti igi ọ̀pẹ sí orí àwọn ìtẹ́lẹ̀ ati ìtẹ́dìí yìí, bí ààyè ti wà fún olukuluku sí; ó sì ṣe òdòdó sí i yípo.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ati lara iha ẹgbẹti rẹ̀, ati leti rẹ̀, li o gbẹ́ aworan kerubu, kiniun, ati igi-ọpẹ gẹgẹ bi aye olukuluku, ati iṣẹ ọṣọ yikakiri.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ó sì gbẹ́ àwòrán kérúbù, kìnnìún àti igi ọ̀pẹ sára ìhà orí rẹ̀ àti sára àlàfo ọ̀nà àárin, ní gbogbo ibi tí àyè wà, pẹ̀lú iṣẹ́ ọ̀ṣọ́ yíkákiri.