1 Kings 7:40 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Huramu mọ ọpọlọpọ ìkòkò, ó fi irin rọ ọkọ́ pupọ, ó sì ṣe àwọn àwo kòtò. Bẹ́ẹ̀ ni ó ṣe parí iṣẹ́ tí ó bá Solomoni ọba ṣe ninu ilé OLUWA.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Hiramu si ṣe ikoko ati ọkọ́, ati awo-koto. Bẹ̃ni Hiramu si pari gbogbo iṣẹ ti o ṣe fun ile Oluwa fun Solomoni ọba:
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ó sì tún ṣe ìkòkò, àti ọkọ́ àti àwo kòtò. Bẹ́ẹ̀ ni Hírámù sì parí gbogbo iṣẹ́ tí ó ṣe fún ilé OLÚWA fún Sólómónì ọba: