1 Kings 7:50 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
àwọn ife ati ọ̀pá tí wọ́n fi ń pa iná ẹnu fìtílà; àwokòtò ati àwo turari, àwo ìfọnná tí wọ́n fi ojúlówó wúrà ṣe, wọ́n fi wúrà ṣe àwọn ihò àgbékọ́ ìlẹ̀kùn Ibi-Mímọ́-Jùlọ ati ti ìlẹ̀kùn gbọ̀ngàn Tẹmpili náà.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ati ọpọ́n, ati alumagaji-fitila, ati awo-koto, ati ṣibi, ati awo turari ti wura daradara; ati agbekọ wura, fun ilẹkun inu ile, ibi mimọ́-julọ, ati fun ilẹkun ile na, ani ti tempili.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ọpọ́n kìkì wúrà, àlùmágàjí fìtílà, àti àwo kòtò, àti ṣíbí àti àwo tùràrí ti wúrà dáradára; àti àgbékọ́ wúrà fún ilẹ̀kùn inú ilé ibi mímọ́ jùlọ àti fún ilẹ̀kùn ilé náà, àní ti tẹ́ḿpìlì.