1 Kings 7:51 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Bẹ́ẹ̀ ni Solomoni ọba ṣe parí gbogbo iṣẹ́ kíkọ́ ilé OLUWA, ó kó gbogbo fadaka, wúrà, ati àwọn ohun èlò inú ilé ìsìn, tí Dafidi, baba rẹ̀, ti yà sí mímọ́ wá, ó sì fi wọ́n pamọ́ sinu àwọn ilé ìṣúra tí ó wà ninu ilé OLUWA.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Bẹ̃ni gbogbo iṣẹ ti Solomoni ọba ṣe fun ile Oluwa pari. Solomoni si mu gbogbo nkan ti Dafidi baba rẹ̀ ti yà si mimọ́ wá; fadaka, ati wura, ati ohun-elo, o si fi wọn sinu iṣura ile Oluwa.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nígbà tí gbogbo iṣẹ́ tí Sólómónì ọba ṣe fún ilé OLÚWA parí, ó mú gbogbo nǹkan tí Dáfídì baba rẹ̀ ti yà sí mímọ́ wá; fàdákà, wúrà àti ohun èlò, ó sì fi wọ́n sínú ìṣúra ilé OLÚWA.