1 Kings 7:9 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Òkúta olówó ńlá, tí wọ́n fi ayùn gé tinú-tẹ̀yìn, ni wọ́n fi kọ́ gbogbo ilé ati àgbàlá rẹ̀, láti ìpìlẹ̀ títí dé òrùlé rẹ̀, ati láti àgbàlá ilé OLUWA títí dé àgbàlá ńlá náà.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Gbogbo wọnyi jẹ okuta iyebiye gẹgẹ bi iwọn okuta gbigbẹ́, ti a fi ayùn rẹ́ ninu ati lode, ani lati ipilẹ de ibori-oke ile, bẹ̃ si ni lode si apa agbala nla.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Gbogbo wọ̀nyí láti òde dé apá àgbàlá ńlá, àti láti ìpìlẹ̀ dé ìbòrí òkè ilé, wọ́n sì jẹ́ òkúta iyebíye gẹ́gẹ́ bí ìwọ̀n òkúta gbígbẹ, tí a fi ayùn rẹ́ nínú àti lóde.