1 Kings 8:1 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Lẹ́yìn náà, Solomoni ọba ranṣẹ sí àwọn àgbààgbà Israẹli: àwọn olórí ẹ̀yà kọ̀ọ̀kan, ati gbogbo àwọn olórí ìdílé kọ̀ọ̀kan, ó pè wọ́n jọ sí Jerusalẹmu láti gbé Àpótí Ẹ̀rí OLUWA láti Sioni, ìlú Dafidi, wá sinu ilé OLÚWA.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
NIGBANA ni Solomoni papejọ awọn agba Israeli, ati gbogbo awọn olori awọn ẹ̀ya, awọn olori awọn baba awọn ọmọ Israeli, si ọdọ Solomoni ọba ni Jerusalemu, ki nwọn ki o lè gbe apoti-ẹri majẹmu Oluwa wá lati ilu Dafidi, ti iṣe Sioni.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nígbà náà ni Sólómónì pe àwọn àgbà Ísírẹ́lì àti gbogbo àwọn olórí àwọn ẹ̀yà àti àwọn olórí ìdílé àwọn ọmọ Ísírẹ́lì jọ papọ̀ níwájú rẹ̀ ní Jérúsálẹ́mù, láti gbé àpótí-ẹ̀rí májẹ̀mú OLÚWA wá láti ìlú Dáfídì, tí ń ṣe Ṣíónì.