1 Kings 8:16 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
‘Láti ìgbà tí mo ti kó àwọn eniyan mi jáde láti ilẹ̀ Ijipti, n kò yan ìlú kan ninu gbogbo ilẹ̀ Israẹli pé kí àwọn ọmọ Israẹli kọ́ ilé ìsìn sibẹ, níbi tí wọn óo ti máa sìn mí, ṣugbọn, mo yan Dafidi láti jọba lórí Israẹli, eniyan mi.’ ”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Lati ọjọ ti emi ti mu Israeli, awọn enia mi jade kuro ni Egipti, emi kò yàn ilu kan ninu gbogbo ẹyà Israeli lati kọ́ ile kan, ki orukọ mi ki o le mã gbe inu rẹ̀: ṣugbọn emi yàn Dafidi ṣe olori Israeli, awọn enia mi.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
‘Láti ọjọ́ tí èmi ti mú àwọn ènìyàn mi Ísírẹ́lì jáde kúrò ní Éjíbítì, èmi kò tí ì yan ìlú kan nínú gbogbo ẹ̀yà Ísírẹ́lì láti kọ́ ilé kan fún orúkọ mi láti wà níbẹ̀, ṣùgbọ́n èmi ti yan Dáfídì láti ṣàkóso àwọn Ísírẹ́lì ènìyàn mi.’