1 Kings 8:23 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Ó bẹ̀rẹ̀ sí gbadura, ó ní, “OLUWA Ọlọrun Israẹli, kò sí Ọlọrun kan tí ó dàbí rẹ̀ lókè ọ̀run tabi ní ayé yìí, tíí máa pa majẹmu rẹ̀ mọ́, tíí sì máa fi ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀ hàn sí àwọn iranṣẹ rẹ̀, tí ń fi tọkàntọkàn gbọ́ràn sí i lẹ́nu.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
O si wipe, Oluwa Ọlọrun Israeli, kò si Ọlọrun ti o dabi rẹ loke ọrun, tabi ni isalẹ ilẹ, ti ipa majẹmu ati ãnu mọ pẹlu awọn iranṣẹ rẹ ti nfi gbogbo ọkàn wọn rin niwaju rẹ:
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ó sì wí pé: “OLÚWA Ọlọ́run Ísírẹ́lì, kò sí Ọlọ́run tí ó dàbí rẹ lókè ọ̀run tàbí ní ìṣàlẹ̀ ilẹ̀ ìwọ tí ó pa májẹ̀mú àti àánú mọ́ pẹ̀lú àwọn ìránṣẹ́ rẹ tí ń fi gbogbo ọkàn wọn rìn níwájú rẹ.