1 Kings 8:25 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Ǹjẹ́ nisinsinyii, OLUWA Ọlọrun Israẹli, mo bẹ̀ ọ́, mú àwọn ìlérí tí o ṣe fún iranṣẹ rẹ, Dafidi, baba mi ṣẹ, pé, arọmọdọmọ rẹ̀ ni yóo máa jọba ní Israẹli títí lae, bí wọ́n bá ṣọ́ra ní ọ̀nà wọn, tí wọ́n sì bá mi rìn bí ìwọ ti bá mi rìn.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Njẹ nisisiyi, Oluwa Ọlọrun Israeli, ba iranṣẹ rẹ Dafidi, baba mi pa ohun ti iwọ ti ṣe ileri fun u mọ́ wipe, A kì yio fẹ ọkunrin kan kù li oju mi lati joko lori itẹ Israeli; kiki bi awọn ọmọ rẹ ba le kiyesi ọ̀na wọn, ki nwọn ki o mã rìn niwaju mi gẹgẹ bi iwọ ti rìn niwaju mi.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
“Ǹjẹ́ báyìí OLÚWA Ọlọ́run Ísírẹ́lì, bá ìránṣẹ́ rẹ̀ Dáfídì bàbá mi pa ohun tí ìwọ ti ṣe ìlérí fún un mọ́ wí pé, Iwọ kì yóò kùnà láti ní ènìyàn kan láti jókòó níwájú mi lórí ìtẹ́ Ísírẹ́lì, kìkì bí àwọn ọmọ rẹ bá lè kíyèsí ohun tí wọ́n ń ṣe láti máa rìn níwájú mi bí ìwọ ti rìn.