1 Kings 8:27 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
“Ṣugbọn, ǹjẹ́ ìwọ Ọlọrun lè gbé inú ayé yìí? Nítorí pé bí gbogbo ọ̀run ti tóbi tó, kò gbà ọ́; kí á má ṣẹ̀ṣẹ̀ sọ ti ilé ìsìn tí mo kọ́ fún ọ?
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ṣugbọn nitõtọ Ọlọrun yio ha mã gbe aiye bi? wò o, ọrun ati ọrun awọn ọrun kò le gbà ọ; ambọ̀sì ile yi ti mo kọ́?
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
“Ṣùgbọ́n nítòótọ́ Ọlọ́run yóò máa gbé ayé bí? Ọ̀run àti ọ̀run àwọn ọ̀run kò le gbà ọ́. Kí a má sọ pé ilé yìí tí mo kọ́ fún ọ!