1 Kings 8:32 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
OLUWA, gbọ́ lọ́run lọ́hùn-ún, kí o sì ṣe ìdájọ́ àwọn iranṣẹ rẹ. Jẹ ẹni tí ó bá jẹ̀bi ní ìyà gẹ́gẹ́ bí ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀; dá ẹni tí ó bá jàre láre, kí o sì san ẹ̀san òdodo rẹ̀ fún un.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nigbana ni ki o gbọ́ li ọrun, ki o si ṣe, ki o si dajọ awọn iranṣẹ rẹ, ni didẹbi fun enia buburu, lati mu ọ̀na rẹ̀ wá si ori rẹ̀; ati ni didare fun olõtọ, lati fun u gẹgẹ bi ododo rẹ̀.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
nígbà náà ni kí o gbọ́ láti ọ̀run, kí o sì ṣe. Kí o sì ṣèdájọ́ láàrin àwọn ìránṣẹ́ rẹ, dá ènìyàn búburú lẹ́bi, kí o sì mú wá sí orí òun tìkára rẹ̀ ohun tí ó ti ṣe, dá olóòtọ́ láre, kí a sì fi ẹṣẹ̀ àìlẹ́bi rẹ̀ múlẹ̀.