1 Kings 8:33 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
“Nígbà tí àwọn ọ̀tá bá ṣẹgun àwọn ọmọ Israẹli, eniyan rẹ, nítorí pé wọ́n dẹ́ṣẹ̀ sí ọ́, lẹ́yìn náà, tí wọ́n bá tún yipada sí ọ, tí wọ́n jẹ́wọ́ orúkọ rẹ ninu ilé yìí, tí wọ́n gbadura sí ọ, tí wọ́n bẹ̀bẹ̀,
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nigbati a ba lù Israeli, enia rẹ bòlẹ niwaju awọn ọ̀ta, nitoriti nwọn dẹṣẹ si ọ, ti nwọn ba si yipada si ọ, ti nwọn si jẹwọ orukọ rẹ, ti nwọn si gbadura, ti nwọn si bẹ̀bẹ lọdọ rẹ ni ile yi:
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
“Nígbà tí àwọn ọ̀tá bá ṣẹ́gun Ísírẹ́lì, ènìyàn rẹ, nítorí tí wọ́n ti ṣẹ̀ sí ọ, tí wọ́n bá yípadà sí ọ, tí wọ́n sì jẹ́wọ́ orúkọ rẹ, tí wọ́n sì gbàdúrà, tí wọ́n sì bẹ̀bẹ̀ lọ́dọ̀ rẹ nínú ilé yìí