1 Kings 8:36 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
gbọ́ adura wọn lọ́run lọ́hùn-ún, dárí ẹ̀ṣẹ̀ ji Israẹli, iranṣẹ rẹ, àní, àwọn eniyan rẹ, kí o sì kọ́ wọn ní ọ̀nà rere tí wọn yóo máa tọ̀; lẹ́yìn náà, rọ òjò sórí ilẹ̀ rẹ tí o fi fún àwọn eniyan rẹ bí ohun ìní.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nigbana ni ki o gbọ́ li ọrun, ki o si dari ẹ̀ṣẹ awọn iranṣẹ rẹ jì, ati ti Israeli, enia rẹ, nigbati o kọ́ wọn li ọ̀na rere ninu eyiti nwọn iba mã rin, ki o si rọ̀ òjo si ilẹ rẹ, ti iwọ ti fi fun enia rẹ ni ilẹ-ini.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
nígbà náà ni kí o gbọ́ láti ọ̀run wá, kí o sì dárí ẹ̀ṣẹ̀ àwọn ìránṣẹ́ rẹ jìn wọ́n, à ní Ísírẹ́lì, ènìyàn rẹ. Kọ́ wọn ní ọ̀nà tí ó tọ́ láti máa rìn, kí o sì rọ òjò sí ilẹ̀ tí ìwọ ti fi fún ènìyàn rẹ fún ìní.