1 Kings 8:37 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
“Nígbà tí ìyàn bá mú ní ilẹ̀ yìí, tabi tí àjàkálẹ̀ àrùn wà, tabi ìrẹ̀dànù èso, tabi tí ọ̀wọ́ eṣú, tabi tí àwọn kòkòrò bá jẹ ohun ọ̀gbìn oko run, tabi tí àwọn ọ̀tá bá dó ti èyíkéyìí ninu ìlú àwọn eniyan rẹ, tabi tí àìsàn, tabi àrùnkárùn kan bá wà láàrin wọn,
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Bi iyàn ba mu ni ilẹ, bi ajakalẹ-arùn ni, tabi ìrẹdanu, tabi bibu, tabi bi ẽṣu tabi bi kòkorò ti njẹrun ba wà; bi ọtá wọn ba dó tì wọn ni ilẹ ilu wọn; ajakalẹ-arùn gbogbo, arùn-ki-arun gbogbo.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
“Nígbà tí ìyàn tàbí àjàkálẹ̀-àrùn bá wá sí ilẹ̀ náà, tàbí ìrẹ̀dànù tàbí ìmúwòdú, eṣú tàbí kòkòrò tí ń jẹni run, tàbí nígbà tí àwọn ọ̀tá bá dó tì wọ́n nínú àwọn ìlú wọn, irú ìpọ́njú tàbí àrùnkárùn tó lè wá,