1 Kings 8:38 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
gbọ́ adura tí wọ́n bá gbà, ati ẹ̀bẹ̀ tí ẹnikẹ́ni tabi gbogbo Israẹli, àwọn eniyan rẹ, bá bẹ̀, nítorí ìpọ́njú ọkàn olukuluku wọn. Tí wọ́n bá gbé ọwọ́ wọn sókè, tí wọ́n sì kọjú sí ilé ìsìn yìí,
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Adura ki adura, ati ẹ̀bẹ ki ẹ̀bẹ, ti a ba ti ọdọ ẹnikan tabi lati ọdọ gbogbo Israeli, enia rẹ gbà, ti olukuluku yio mọ̀ ibanujẹ ọkàn ara rẹ̀, bi o ba si tẹ́ ọwọ́ rẹ̀ mejeji si iha ile yi!
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
nígbà tí àdúrà tàbí ẹ̀bẹ̀ bá ti ọ̀dọ̀ ẹnìkan láti ọ̀dọ̀ gbogbo Ísírẹ́lì wá, tí olúkúlùkù sì mọ ìbànújẹ́ ọkàn rẹ̀, bí ó bá sì tẹ́ ọwọ́ rẹ̀ méjèèjì sí ìhà ilé yìí,