1 Kings 8:39 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
gbọ́ adura wọn láti ibùgbé rẹ lọ́run, dáríjì wọ́n, dá wọn lóhùn, kí o sì san ẹ̀san fún olukuluku gẹ́gẹ́ bí iṣẹ́ rẹ̀, (nítorí ìwọ nìkan ni o mọ èrò ọkàn ọmọ eniyan);
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nigbana ni ki iwọ ki o gbọ́ li ọrun, ibugbe rẹ, ki o si darijì, ki o si ṣe ki o si fun olukulùku enia gẹgẹ bi ọ̀na rẹ̀, ọkàn ẹniti iwọ mọ̀; nitoriti iwọ, iwọ nikanṣoṣo li o mọ̀ ọkàn gbogbo awọn ọmọ enia;
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
nígbà náà ni kí o gbọ́ láti ọ̀run wá, ní ibùgbé rẹ. Dáríjìn, kí o sì ṣe sí olúkúlùkù ènìyàn gẹ́gẹ́ bí gbogbo ohun tí ó ti ṣe, níwọ̀n ìgbà tí ìwọ mọ ọkàn rẹ̀, nítorí ìwọ nìkan ṣoṣo ni ó mọ ọkàn gbogbo ènìyàn,