1 Kings 8:43 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
gbọ́ adura rẹ̀ láti ibùgbé rẹ lọ́run, kí o sì ṣe gbogbo ohun tí ó bá bèèrè fún un, kí gbogbo aráyé lè mọ orúkọ rẹ, kí wọ́n sì lè bẹ̀rù rẹ bí àwọn ọmọ Israẹli, àwọn eniyan rẹ tí ń ṣe, wọn yóo sì mọ̀ pé ilé ìsìn rẹ ni ilé tí mo kọ́ yìí.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Iwọ gbọ́ li ọrun, ibùgbe rẹ, ki o si ṣe gẹgẹ bi gbogbo eyiti alejò na yio ke pè ọ si: ki gbogbo aiye ki o lè mọ̀ orukọ rẹ, ki nwọn ki o lè mã bẹ̀ru rẹ, gẹgẹ bi Israeli, enia rẹ, ki nwọn ki o si lè mọ̀ pe: orukọ rẹ li a fi npè ile yi ti mo kọ́.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
nígbà náà ni kí o gbọ́ láti ọ̀run wá, ní ibùgbé rẹ, kí o sì ṣe gbogbo èyí tí àlejò náà yóò bèèrè lọ́wọ́ rẹ, kí gbogbo ènìyàn ní ayé lè mọ orúkọ rẹ, kí wọn kí ó sì máa bẹ̀rù rẹ, gẹ́gẹ́ bí Ísírẹ́lì, ènìyàn rẹ ti ṣe, kí wọn kí ó sì le mọ̀ pé orúkọ rẹ ni a fi pe ilé yìí tí mo kọ́.