1 Kings 8:48 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
tí wọ́n bá ronupiwada tọkàntọkàn ní ilẹ̀ àwọn ọ̀tá wọn tí ó kó wọn lẹ́rú, tí wọ́n bá kọjú sí ilẹ̀ tí o fi fún àwọn baba ńlá wọn, ati ìlú tí o yàn yìí, ati ilé ìsìn tí mo kọ́ ní orúkọ rẹ, tí wọ́n bá gbadura sí ọ;
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Bi nwọn ba si fi gbogbo àiya ati gbogbo ọkàn wọn yipada si ọ ni ilẹ awọn ọta wọn, ti o kó wọn ni igbèkun lọ, ti nwọn si gbadura si ọ siha ilẹ wọn, ti iwọ ti fi fun awọn baba wọn, ilu ti iwọ ti yàn, ati ile ti emi kọ́ fun orukọ rẹ:
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
bí wọ́n bá sì fi gbogbo àyà àti gbogbo ọkàn wọn yípadà sí ọ, ní ilẹ̀ àwọn ọ̀tá wọn, tí ó kó wọn ní ìgbèkùn lọ, tí wọ́n sì gbàdúrà sí ọ sí ìhà ilẹ̀ wọn tí ìwọ ti fi fún àwọn baba wọn, Ìlú tí ìwọ ti yàn, àti ilé tí èmi kọ́ fún orúkọ rẹ;